Jimoh:- NAFDAC yoo gbogunti ayedeeru ohun-eelo nipa imo ero

0
215

Ajo ijoba apapo Naijiria to n risi oro ohun jije ati oogun lilo (NAFDAC) ti ni won yoo safikun imo lorisirisii ona ero igbalode lati maa fi sayewo awon nnkan ayedeeru lorile-ede Naijiria. Oludari eka ise akanse, Ogbeni Abubakar Jimoh, lo soro yii nilu Abuja lojo’Bo.

Jimoh soro lori lilo ona igbalode ati imo ero to ye kooro gege bi won se n se nile okeere. O ni ajo NAFDAC ti pari eto lati bere si ni dan awon ero naa wo bii eyi ti won pe ni black and gold, ati track and trace ti won fi n sayewo ayedeeru nnkan nile okeere.

O ni lateyin wa, a maa n ko awon ayewo wa lo sile ayewo igbalode ni, ni eyi to maa n gba wa to ose meji si meta ki a to ri esi gba, ni eyi to maa n mu ifura dani lodo awon apoogun ti won maa n fi esun kan ajo NAFDAC nigba mii pe won n yi esi ayewo naa. sugbon lowo yii, ni kete ti a ba ti sayewo ni esi re ti n jade.”

Jimoh, to je agbenuso ajo naa ni lodun 2010 ni ajo NAFDAC bere si ni lo ero ayewo kan eyi ti won pe ni truscan ati anti-mobile authentication technology services eyi ti won fi n sayewo fun ayedeeru oogun.

Ni ipari, Jimoh ni ajo NAFDAC ti pari eto lati tun awon ibudo ayewo se kaakiri orile-ede yii ki ajo naa le sise bi o ti ye.

LEAVE A REPLY