Kata-kara oja owo-Forex ri o le nirinwo milionu dola gba sii lowo CBN

0
9405

Lojo Eti yii ni banki ile Naijiria, CBN safikun owo idokowo ninu oja owo ile okeere karakata Forex laarin awon ile ifowopamo pelu o le die ni milionu mejilelogota le nirinwo owo dola ile okeere.

Igbese yii je okan lara ipinnu lati tubo je ki ipin idokowo pelu oja ile okeere wa bureke sii ninu eto oro aje Naijiria. Akosile ona pinpin owo naa fihan pe awon olokowo abode SMIS lo ri ipin to po julo gba pelu igba milionu owo dola to le ni egberun lona metadinlaadorin ati die.

Bakan naa ni banki Naijiria, CBN, tun safikun ogorun milionu dola sokowo tawon olokowo nlanla nigba ti awon olokowo keekeeke ri aadota milionu dola gba sinu okowo forex won.

Awon to nilo pasipaaro owo ile okeere fun eto eko, irinajo fun okowo sise, owo fun eto ilera won ati bee bee lo ri milionu marundinlaadota owo dola gba.

Pataki igbese yii si daadaa:

Ogbeni Isaac Okorafor to je adele oludari eka ibanisoro atifitonileti fun banki Naijira ninu awon olori banki CBN dun si eso rere ti won ti n foju ri lori isele inu pasipaaro owo okowo forex lorile ede yii lowolowo paapaa ni eka agbe, ati awon to n sohun eelo kaakiri Naijiria.

Lasiko to n jeri si ona pinpin owo yii lo menuba idagbasoke to ti de ba awon eka ti kii se tepo robi ni eyi to ti mu idagbasoke de ba ise ogbin ni Pataki julo bayii.

Ni afikun, adele oludari eka naa ni banki Naijiria ko ni reyin ninu igbiyanju re lati mu ki pasipaaro owo tubo rorun sii nipa sisamojuto to ye sigbese inu eka NAFEX to n risi oro pasipaaro owo bayii ati eka Bureu de change, BDC, awon aladani to n se katakara pelu owo ile okeere.

Ni ipari, o tenumo ipinnu ti gomina banki naa, iyen, Godwin Emefiele soro lori lojo Isegun to koja nipa ireti pe gbogbo igbese akoni wonyii yoo da oro aje Naijiria pada si ti tele laipe.

Bayii pasipaaro owo naira Naijiria si dola ile America si wa ni oodunrun naira le logota si owo dola kan lodo awon olokowo pasipaaro BDC.

 

 

LEAVE A REPLY