Kogi gboriyin fawon olugbe re fun sisatileyin fun eto kole-kodoti

0
9295

Ijoba ipinle Kogi ti fidunun han lori bi awon olugbe ipinle naa se tewogba eto kole-kodoti tijoba gunle yii. Ijoba gboriyin fawon eniyan kaakiri egbe kookan ati agbegbe kookan lori eto gbale-gbata ohun.

Komisona fun awujo ati ohun alumooni, Abileko Rosemary Osikoya lo soro yii ni Lokoja to je olu-ilu ipinle naa. Osikoya fidunun re han pe awon eniyan ti n nimo kikun lori igbiyanju ijoba lori idoti. O ni:

Fun apeere, ijo irapada ti Kristi RCCG ekun keta nipinle ohun ti kowe ranse si wa pe awon setan lati ran ogorun omo ijo won wa kopa ninu eto gbale-gbata naa fun osu kefa odun. Fafiti apapo ti Lokoja naa ti seleri aadota akekoo, o kere tan, bee naa ni, egbe awon obinrin Otokiti ati Zango pelu awon odo Zango ati Zariagi naa ti seleri lati kopa ninu eto kole-kodoti naa”

O nijoba ipinle ohun ti keko lataari igbese ateyinwa ni eyi ti yoo je ki ise naa yori si rere bayii. Komisona ni: Erongba wa ni lati din idoti to to ida meedogun ninu ogorun un ku lodun kaakiri ipinle yii ki a le ni agbegbe to mo, ti ko leeri, ti ko faaye gba aisan”

Komisona naa ni eto gbale-gbadoti tosu kefa yii ni yoo je eleekerinla iru re leyin ti gomina ipinle ohun, Alahaji Yahaya Bello ti se ifilole eto naa lojo keedogbon osu karun un odun 2016.

O ni owo tijoba ya soto ninu eto isuna ipinle naa ti n bi eso rere, ni eyi ti okiti ile ti n dawati bayii nipinle naa. Komisona Rosemary ro awon eniyan ipinle Kogi lati tu yaaya jade gbale-gbata nipari osu yii

LEAVE A REPLY