Macron yan awon obinrin fun ida meji minista tuntun re

0
471

Aare tuntun ti won yan lorile-ede Faranse, Emmanuel Macro, ti siso loju eegun ipinnu re lati ma segbe fun awon kan ninu yiyan awon eniyan sipo. Mokanla ninu awon minista mejilelogun to yan je obinrin nigba ti awon mokanla to ku naa je Okunrin.

Sylvie Goulard je minista fun eto aabo, Olympic fencing champion Laura Flessel je minista fun ere idaraya. Bruno Le Maire je ti eto oro aje, Gérard Collombje ti oro abele nigba ti François Bayrou je ti eto idajo.

Bi Macron se yan won kaakiri yii ti da rugudu sile nile Faranse. Ogbeni Le Maire je ti awon ti atijo, Ogbeni Collomb je olori fun amuludun ni Lyon nigba ti Ogbeni Bayrou je ogbontarigi ologun.

Awon kan ti koko bu enu ate lu Macron atawon ti won ba a bowo lu iwe to fi yan awon eniyan sipo tele. Eni kan ni nise lo n fe agbo oselu siwaju sii ni eyi to le di wahala.

Aare ile Faranse tuntun gbagbo pe awon to yan sipo yoo sise bi o ti ye nipa didibo fawon to ye losu to m bo.

Awon minista miran to yan ni: Jean-Yves Le Drian, ti eto aabo labe aare François Hollande, eni to maa di minista fun ile okeere. Nicolas Hulot, to mo nipa oju ojo ti yoo di minista imo nipa abemi.

Richard Ferrand to je okan pataki lara awon olupolongo fun Macron naa gba ipo. Awon to ku ni:

  • Agnès Buzyn – minista eto ilera
  • Murielle Pénicaud – Oro ise
  • Mounir Mahjoubi – minista kekere fun oro igbalode
  • Françoise Nyssen – Asa
  • Jean-Michel Blanquer – Eto eko
  • Jacques Mézard – Ise agbe ati ohun jije

Marlène Schiappa, di minista kekere fun ogboogba laarin awon okunrin ati obinrin.

Ohun ijoloju ibe ni pe ni kete ti Ogbeni Macron yan Edouard Philippe gege bi olori orile-ede naa lojo Aje ni awon agba atijo oloselu to to ida aadosan ti ni won sese n ri ayipada mii ninu oselu ni.

Saaju eto idibo awon omo asofin losu kefa ni oloye ninu egbe oselu Republican, François Baroin ti fesun kan Macron pe o n dena mo fila ni bo se n yan orisiirisii awon eniyan wonyii.

LEAVE A REPLY