Naijiria gboriyin fun ajo agbaye U.N. fun iranlowo lori igbogun-ti boko-haram

0
744

Orile-ede Naijiria ti gboriyin fun ajo agbaye, United Nations, lori akitiyan won lati sise papo fun gbigbogun ti awon boko haram pelu ona iranlowo ti won n se lati ran awon asatipo lowo. Akowe agba fun ile ise ijoba to n mojuto oro ile okeere, Sola Enikanolaye lo soro yii lasiko ti o sabewo si ofiisi igbakeji akowe ajo naa, Amina Mohammed ni New York.

Enikanolaiye ki awon alajosisepo pelu ajo agbaye lori akyiyan won lori pipese awon ohun eelo iranlowo fun fawon ti ogun boko haram so di alaini lapa oke oya Naijiria.

 “A fe ki ajo agbaye daadaa fun ise akoni ti won n se lapa ariwa orile ede yii. Afi n da ajo naa loju pe ijoba yoo tubo sa ipa won lati pese eto aabo to ye fawon ara ilu ati ipese awon ohun amayederun fun won, pelu ona ipamo fawon osise eleto iranwo ati ajo lorisiirisii”

Bakan naa lo ki ajo naa loruko Naijiria fun atunse si ile Ogoni.

Ajosepo olojo pipe:

Enikanolaiye menuba erongba ijoba Naijiria pe won ti setan lati tubo sise pelu ajo agbaye  paapaa lori isoro ekun Naija-Delta. Eyi to seese nipa ona ibara eni soro pelu ewu inu afefe ati agbegbe kookan.

Bakan naa lo ki won fun igbese akoni lori oro Lake Chad ati idagbasoke igberiko ni ekun naa. Nipari lo ro ajo agbaye lati tubo sise sii fun iranlowo fawon eniyan ile Adulawo.

LEAVE A REPLY