Naijiria se ifilole ipolongo owo-ori kaakiri

0
9782

Ile ise ijoba apapo to n ri si owo wiwole, Federal Inland Revenue Service (FIRS) ti bere eto ipolongo lati je ki awon eniyan orile-ede yii mo nipa pataki sisan owo ori. Won pe ipolongo yii ni eyi ti o wa fun VAIDS to je ona sisafihan ohun ini re ati sisan owo-ori to ye lori owo to n wole fun koowa.

Awon iko to n polongo naa sabewo soja, awon ile itaja nlanla ki won le ko awon eniyan leko paapaa awon iyaloja lori sisan owo-ori ati anfaani to ro mo sisan an lasiko.

Ogbeni Babatunde Fowler to je alaga FIRS lo siso loju eto naa nilu Abuja ni asiko ti to kijoba safikun si ona towo n gba wole pe ipolongo naa yoo maa waye lojo Bo ki won le mo nipa pataki owo ori.

Ogbeni Fowler ni pataki erongba yii ni pe:A bere eto VAIDS yii ki gbogbo eniyan le ni oore ofe lati so awon ohun ini won ati oye owo-oya won ki won le san odiwon iye owo ori to te ki Naijiria le sun soke. Eyi yoo je ki ala Naijiria di mimuse. E je ki a fowosopo nipa sisan owo ori to ye ki a le rowo fi so ala wa di iran otun”

Ogbeni Edozie Ogwu to je alaga egbe awon ontaja fun Naijiria ninu oro re ni o ye kijoba sise po pelu awon ontaja lati yii ero won pada lori owo ori sisan pe: A fe ro won ki won fowosopo pelu wa ni awon ona kookan lasiko yii ti a ti setan lati sanwo ori wa nitori pe a mo pe laisi owo idagbasoke to ye ko le wa. A dupe fun anfaani ti e fun wa lati sise lori odiwon owo ori wa bi o ti ye”

Ogbeni Ugwu salaye pe eto VAIDS yii yoo fawon eniyan to ti je gbese owo ori tele laaye lati sanwo ori naa fun ijoba pada laarin ojo kinni osu keje odun 2017 si ojo kokanlelogbon osu keta odun 2018.

O ni fawon to ba san gbese odiwon ti won je pelu oooto inu, ijoba seleri lati mojukuro ninu ijiya to ye ki won bu fun won pelu owo ele ori e to ye ki won san sori owo ori ti won ti je tele.

Owo ori Lowolowo je ida mefa ninu ida ogorun un ni eyi tawon orile ede to ti goke agba je laarin ida ogbon si mejilelogbon ninu ogorun un.

 

LEAVE A REPLY