Naijiria ti bo lowo arun yirunyirun

0
9137

Ibudo alamojuto arun to tun n gbogunti itankale arun lorile-ede Naijiria (NCDC) soro nilu Abuja to je olu-ilu Naijiria pe Naijiria ti bo lowo itankale arun yirunyirun to besile lodun 2016 si 2017.

Gege bi won se so ninu atejade ti NCDC fi sita pe: “Lati nkan bii ose mejo ni arun naa ti n dinku ti awon ipinle to ti sele si ti n ri isele otun ni prerete. Laarin ose merin to koja ko sijoba ibile kankan to ti pe fun pajawiri pe won tun ri isele tuntun. Nigba to fi maa di ojo kerindinlogun osu kefa odun 2017 ni ajo EOC so pe Naijiria bo, lataari pe ko si akosile fun tuntun mo. ki won to se ikede yii, o le ni eedegberun le ni egberun merinla isele afurasi ni won ri nipinle meedogbon ni eyi to ja si iku to je ida mejo ninu ogorun un to ja si iku eniyan merindinlaadojo to le ni egberun kan”

Ajo NCDC ni won sise papo pelu ajo to n ri si idagbasoke eto ilera alabode NPHCDA atawon ajo miran lati tete wagbo dekun fiun itankale arun naa kaakiri

Lori amojuto isele arun pajawiri naa

Ggege bi adari ajo NCDC, Onisegun oyinbo Chikwe Ihekweazu se salaye pe: “Nitooto ni ajo NCDC ti sise lati gbogunti itankale arun ohun, sibe ise naa ko tii pari ni wakati kookan lojoojumo nitori pe aabo gbogbo eniyan Naijria kuro lowo arun se koko. A gboriyin fun awon olori wa to je minista fun eto ilera ati awon adari eka amojuto ilera alabode ati ipese won fun ajosepo to ajo se lasiko ti arun ohun n tankale. Ajo NCDC gbe ibudo isele pajawiri kale kaakiri pelu iko ti won n tete dahun sipe isele pajawiri ni awon ipinle ti oro kan ki ona igbogunti naa le ya, ki ifitonileti le tete de gbogbo ibudo to ye. eyi to je ki awon gbongan ayewo naa si sise lasiko”

Omowe Ihekwazu ni igbese wonyii ni lati dena irufe iselle bee lojo iwaju ki a le tete mojutoo ko to maa gbebo lowo wa. O menuba awon ibudo ayewo nla atiseiwadii ti won sese gbe kale si Gaduwa nilu Abuja pelu atileyin ile ise ijoba apapo to n mojuto eto ilera, pelu USCDC to n mojuto itankale arun nile America ati ajo ilera agbaye WHO

Awon ilana aatele lapapo

Onisegun oyinbo yii ni ajo NCDC tun n ri si ise ibudo ayewo kaakiri orile-ede Naijiria ki won le tete maa da isele arun kookan mo ni kiakia lati dena de arun miran. Ni afikun, awon ilana aatele ti wa ti a ti sagbekale re ki a le fi tete mojuto irufe isele pajawiri bayii pelu ipolongo loorekoore.

Bakan naa, ni a n gbe igbese lati se idanilekoo ati iseto ipolongo abere ajesara ti ajo NPHCDA fi saseyori ni awon ipinle Zamfara, Sokoto, Yobe ati Katsina

Bee naa la n sise po pelu awon ijoba ipinle lori ipolongo ki won le ri i pe abere ajesara naa de gbogbo igberiko to ye. Onisegun oyinbo Ihekweazu ni: “A dupe pupo lowo ijoba ipinle Zamfara ati Sokoto fun igbese akoni won lasiko ti arun yirunyirun yii be sile lekun naa. A tun dupe lowo ajo ilera agbaye WHO to je alajosisepo wa ati ajo igbogunti itankale arun nile Adulawo ACDC pelu tile America atawon ajo to n ri si iwonu iwadii arun ati fafiti ile eko giga Maryland ni Baltimore nile America fun atileyin won”

LEAVE A REPLY