Naijiria yoo maa pese iresi toto fun ara ilu titi odun 2018

0
25

Oloye Audu Ogbeh, to je minista fun ise agbe ati idagbasoke igberiko fun orile ede Naijiria ti ni ijoba apapo n sa ipa re lati rii pe ko to di odun 2018, Naijiria yoo maa pese odiwon iresi ti ara ilu nilo. Ogbeh soro yii nibi iforowero pelu ile ise eto iroyin fun Naijiria nilu Abuja.

O ni eyi seese latari igbiyanju awon agbe. O ni: “Lakoko, mo fe ki awon omo Naijiria ku oriire pea won agbe ji giri si ise ogbin paapaa lasiko odun keresi to koja. Bayii, awon eniyan Naijiria ti mop e iresi ti a gbin ni bi san ju tile okeere bii Thailand, ati Vietnam ni awon eyi to je olupese iresi julo lagbaye.

Awon eniyan ile Thailand kii je iresi alatunse bikose funfun ni eyi to han pe gbogbo iresi alatunse won ni won n ko sowo si Naijiria.

Naijiria lo n je iresi julo lagbaye, bayii, a ti setan lati figa gbaga pelu awon orile ede agbaye to ku. Eyi yoo pese ise fun awon odo wa.

Bakan naa ni minista salaye lori awon igbese akoni ti ijoba n gbe lati mu aye rorun fawon agbe ki ise won le tubo yo. O ni lowolowo, Naijiria ti n fi iresi sowo si orile ede Cameroun. Niger, Chad ati Mauritan.

 

SHARE

Fi èsì sílẹ̀