NPFL: Rivers United gbaa ami ayo kookan pelu Katsina United

Tobi Sangotola.

0
132
Rivers-united

Iko agba-boolu Rivers United padanu aye won lati bo soke ninu idije boolu afesegba lorile-ede Naijiria, leyin ti won gbaa ami ayo kookan pelu iko agba-boolu Katsina United ni ilu Port Harcourt, lojo aje(Monday).

Rivers United wa ni ipo mejidinlogun pelu ami mejilelogoji lori tabili idije NPFL, ti Katsina United si wa soke lati ipo metadinlogun si ipo merindinlogun pelu ami metalelogoji.

Ni bayii, iko agba-boolu Rivers United ti gbaa ifesewonse merin otooto le ra lai yege rara.

Atamatase agba owo iwaju fun iko agba-boolu orile-ede Mali, Abdoulaye Kanoute lo gba ami ayo wole fun iko Rivers United niseju merinlelogoji saa akoko ifesewonse naa.

Martins Usule agba-boolu iko Katsina United da ami ayo ohun pada niseju metalelaadorun kii ifesewonse ohun bo si ipari.

 

Tobi Sangotola.

LEAVE A REPLY