O seese ki Colombia salaigba ibo Venezuela

0
9165

Aare orile-ede Colombia, Juan Manuel Sani, ni orile-ede oun ko ni gba esi idibo ojo Aiku ti Venezuela yoo fi yan awon asoju to lagbara lati satunse si ilana ofin won.

O ni: “Awon igbimo naa ko bofinmu to ni eyi ti a ko ni fi gba esi idibo naa”

Aare ile Venezuela, Nicolás Maduro pe fun idibo naa nigba ti opo ero n fehonuhan sijoba re losu karun un odun yii. Awon egbe alatako gba pe igbese yii dabi ti alase ni, eyi ti ko bofunmu.

Awon igbimo tuntun yii je ti elenu marundinlaadota o le ni eedegberun omo ile ni eyi to tako ile igbimo asofin ile naa eyi ti awon alatako n dari.

Aare Santos ni, a n beere fun igbese yiyanju aawo pelu alaafia fun orile-ede naa ni.

O kere tan, awon meji ni won farapa nigba ti awon agbofinro ju afefe tajutaju ati ibon roba saarin awon oluwode ni olu ilu Venezuela, iyen Caracas lojo Eti to koja lasiko tawon alatako di opopona.

Ile Venezuela ti fofin de iwode lati osu kerin odun ni eyi to le sakoba fun eto idibo naa bayii.

Ilana ogba ewon bayii ni Venezuela

Minista abele fun Venezuela, Néstor Reverol ti ni o seese ki enikeni to ba tapa sofin iwode fi ewon odun marun un si mewaa ju ara. Lojo Bo to koja ni o ni ofin yii yoo tubo fese mule di ojo Isegun to m bo. O le ni eniyan ogorun ti won ti gbemi mi lataari wahala to n sele lati osu kerin odun.

Rogbodiyan yi ti le debi pe orile ede America ti pase pe ki awon eniyan re to n gbe ni Caracas kuro ni orile-ede naa ati pe ki awon osise to ba wu naa kuro nibe.

Ogbeni Maduro ni ki alatako oun fi ojuna sile pelu irorun nitori pe oun ti setan pe ki won jo joko ijiroro alaafia ni wakati die sii. Lojo Ru ni ile America fofin de awon metala to je agba oje ni Venezuela pelu Ogbeni Reverol to je adari kan ni Venezuela.

Ofin yi de eru awon toro kan to wa ni orile-ede America bakan naa lo fofin de awon eniyan ile America lati bawon dowopo. Aare Donald Trump ile America seleri igbese akoni to mu eto oro aje dani logan ti won ba tesiwaju pelu idibo naa.

Ogbeni Maduro benu ate lu igbese ile America pe won fe nikan maa dari agbaye ni nitori pe ko ba ofin mu rara ati pe iru re ko tii sele ri.

 

 

LEAVE A REPLY