Ohun Ò̩gbìn ni Naijiria yoo fi borí ò̩dá to ń s̩e̩lè̩

0
16

Agbenuso fun Aare, Garba Shehu ni igbese ijoba lati mojuto ise agbe ti n bi eso rere lati koju oda to n koju eto oro aje Naijiria lowolowo.
O ni opolopo Iresi ni Naijiria ti n ri ko ni ere loko ni eyi to ti safikun si owo ileokeere Naijiria. O ni lodun 2014 ni Naijiria gbe iresi toonu milionu kan ati mejo wole yato si todun 2015 to je egberun mejidinlogota.
O ni ogbin iresi mumu lokan aya banki Naijiria ti won n pese ohun to ye fawon agbe ni eyi ti o ti yi naijiria pada kuro ni eni to n gbe iresi wole julo tele.O menuba igbese ijoba eyi to ti je ki apo ajinle dinwo lati egberun mesan si egberun marun abo owo naira.
O ni: Bayii Naijiria ti ni mejilelogbon ibi ipo ajile ti won ko sise tele ni eyi to ilaji won ti bere ise bayii to osise orisii meta n sise lojumo ni eyi to ti pese ise fun opo yanturu eniyan.
Garba benu ate lu bi awon kan se ko lati ri ise rere to n lo lowo nile ise ijoba kaakiri sugbon ti won n kolu awon igbese ijoba lorisiirisi. Awon wonyii je eekan to ri jaje bee ijoba n gbiyanju fawon ti owo won ko tii to eti.
Won ko fe soro lori igbese ipese ina monamona bii ti Mambila ati tawon alajosepo pelu orile ede China lorisiirisi bii ti reluwe

SHARE

Fi èsì sílẹ̀