Olori egbe-oselu alatako Zambia da oko awon olopaa pada

Osundiya Ronke/Tobi Sangotola

0
324

Olori egbe oselu alatako lorile-ede Zambia, Ogbeni Hakainde Hichilema ko lati wo oko awon olopaa ti o ye ki o gbe e pada si ogba ewon, titi di igba ti won yoo fi se ejo esun ti won fi kan-an.

Iroyin so wi pe, olori egbe oselu naa, United Party for National Development (UPND), ko ja le lati wo oko awon olopaa naa latari  ito ati igbe aja ti o kun inu oko naa.

Pelu gbogbo akitiyan awon olopaa lati fi omi fo inu oko naa sibe, oorun naa n posi ni, eyi ti o mu ki awon olopaa da awon odaran na pada si ile-ejo, ti won si fi oko miran gbe won lo titi di asiko igbejo miran.

Ile-ejo ni ilu Lusaka ti o n da ejo yi, ti sun igbejo naa si ojo kankanla osu kanrun odun yi, lati mo bo ya won a gbe ejo olori egbe oselu alatako naa losi ile-ejo to ga julo latari esun ti won fi kan pe o fe gba ipo lowo ijoba aare Edgar Lungu ni tipatipa..

Losu to koja, won mu Ogbeni Hichilema latari pe awon oko re ko  lati yago fun awon oko to n gbe aare koja loju popona lo..

Odaran yii, Ogbeni Hakainde Hichilema, ni won fi esun kan, ti won si mu u, eyi kii se igba akoko re, O wa ni ogba ewon ninu osu kewaa odun to koja lataari esun ti won fi kan an pe o n ko awon igbimo olote jo.

 

Tobi/Ronke

LEAVE A REPLY