Orile-ede Côte d’Ivoire ti yan Kolo Toure, gege bi igbakeji akonimogba iko agba-boolu won

Tobi Sangotola.

0
749
kolo-toure

Agba-boolu iko Arsenal ati iko Liverpool tele ri Kolo Toure,  ni won ti yan bayii lorile-ede Côte d’Ivoire gege bi igbakeji akonimogba iko agba-boolu orile-ede naa.

Egbe to n ri si ere idaraya boolu afesegba lorile-ede Côte d’Ivoire lo so eyi di mimo lana ode yii, ti won si ni ki o bere ise ni kiakia.

Agba-boolu iko orile-ede ohun tele ri, ti o je omo odun merindinlogoji, loti gba iwe-ase akonimogba ti UEFA B, fun idi eyi ni egbe to n ri si boolu afesegba lorile-ede ohun fi yan gege bi igbakeji Ibrahim Kamara ti o je akonimogba agba iko naa.

Kolo Toure, ni o je agba-boolu ti o lami-laaka lagbaye, beeni o ti gba boolu fun orisirisi iko bii Manchester City, Celtic, Liverpool, Arsenal ati bebe lo.

Egbe ohun fi kun oro re pe,” Kolo Toure yoo sise gebe bi igbakeji akonimogba ti yoo ko iko agba-boolu orile-ede naa Elephant Warriors lo si ifesewonse ipegede idije boolu ile Afrika ti won yoo maa gba pelu iko agba-boolu orile-ede Niger.

Toure gba ami ayo meje wole fun orile-ede re ninu ifesewonse ti o le ni ogorun to gba fun iko agba-boolu naa.

Beeni, o kopa ninu idije boolu ile Afrika nigba meje otooto, bakan naa lo tun kopa nigba meta otooto fun idije boolu afesegba lagbaye.

“Aare egbe to n ri si boolu afesegba lorile-ede ohun (FIF) so pe, awon yoo fun ni atileyin ti o peye, beeni eleyi yoo tun wa lara ikeko bi won se n koni mogba re.

“Ni afikun, Toure tun ni iwe-ase akonimogba ti UEFA keji (UEFA B License).

Beeni, yoo sise lati ran akonimogba agba iko naa lowo, KAMARA Ibrahim lati ko iko agba-boolu CHAN ti o orile-ede naa lo si idije CHAN to n bo lona. Eyi yoo fun lanfani ati maa gbaradi lati gba iwe-ase akonimogba kini  UEFA A license.

 

Tobi Sangotola.

LEAVE A REPLY