Orile ede Japan kedun pelu America nibudo awon omo ogun oju omi

0
33
Aare Obama ile America ati Shinzo Abe niudo omo ogun oju omi

Akowe agba fun orile ede Japan, Shinzo Abe ti sabewo ibanikedun si Pearl Harbor ni ile America nibi to ti fedun okan re han lori awon ti won kan agbako nibi ikolu to sele nibudo awon omo ogun oju omi lodun marundinlogorin seyin.

Aare Barack Obama wa lara awon to koworin pelu Abe lo si ibudo naa nibi ti o ti ni a ko gbodo tun ri iru ohun ibanuje bayii mo. O le ni irinwo le ni egberun meji omo ile America to padanu emi won nibudo awon omo ogun naa.

Abe kedun iku awon eniyan naa to sele lodun 1941 lasiko to n gbe ododo ibanikedun  sibe. Bakan naa lo yonbo awon igbese alaafia ti orile ede America n gbe lagbaye lapaapo leyin ti won ti duro iseju kan fawon alaisi

Fi èsì sílẹ̀