Orile-Ede Naijiria Bere Sise Amulo Ilana Iran Tuntun Fun Ekun Niger- Delta

Abiodun Popoola.

0
292
Sise Amulo Ilana Iran Tuntun Fun Ekun Niger- Delta

Ijoba orile-ede Naijiria ati egbe kan lati ekun Niger- Delta ti a mo si Pan Niger Delta Forum, (PANDEF) yo sise papo lati ri wipe erongba igba otun ni ekun Niger- Delta wa si imuse.

Ajo PANDEF yo fowosowopo pelu igbimo kan eyi ti ijoba apapo gbe kale labe ile ise to nrisi awon oro to ni ise pelu ekun naa.

Eyi je okan gboogi,lara awon ifenuko to waye ninu ipade eyi ti ijoba apaapo ati awon adari ekun se labe ajo PANDEF.

Lakoko to nsoro nibi ipade naa ,Adele Aare Yemi Osinbajo, ki awon omo Ajo naa kaabo sinu igbimo naa, o wa tenumo ipinnu ijoba apaapo lati mu igbe aye otun ba ekun Niger Delta pelu ifowosowopo ijoba apaapo, ipinleeka aladani ati awon ilu kereje wa.

O tesiwaju wi pe, ijoba apaapo yo ri wipe eyi wa si imuse lojuna ati ri wipe gbogbo awon ti oro naa kan ni won je anfaani eyi.

Agbarijopo egbe yi kun fun awon asoju lati awon ile ise ijoba, pelu awon ipinle ti oro naa kan, ati pelu ijoba apaapo, eyi ti Adele Aare n dari loju ona ati mu igbe aye irorun deba mutumuwa ni ekun Niger Delta.

O so siwaju wi pe , ijoba apapo ko ni fowo yepere mu eto idariji fun awon omo ogun olote ekun Niger Delta, idasile ile eko giga Fafiti Maritime, sise afomo ilu Ogoni ati apapo ekun Niger Delta.

Oloye Edwin Clark, ti o dari awon Ajo PANDEF, dupe gidigidi lowo ijoba apapo fun edun okan ati ipinnu won lati ri wipe igbe aye otun de ba ekun ohun, eyi ti o si se akiyesi abewo adele Aare si agbegbe naa,eyi ti o mu ki alaafia tubo nipon si ni ekun naa.

“Ogbeni Clark so wi pe, ipade yi yo ri si rere, a se ipade pelu adele Aare,o so otito nipa ohun gbogbo to wa ye, a fenuko lori awon oro kan,a so awon ona abayo ti a wa ronu nipa re, adele Aare je eniyan ti o tutu,a si setan lati atileyin fun,inu wa dun pupo,a ko se amulo ote,sugbon afenuko wa ye laarin won.”

Bakan naa ni minisita fun oro abele lori epo robi Ibe Kachikwu so wi pe, ipade naa waye laisi aawo kankan

Awon adari ekun Niger Delta lati ipinle Akwa Ibom, Bayelsa, Cross River, Delta, Edo ati ipinle Rivers ni o peeju sibi ipade ohun.

 

Abiodun Popoola.

LEAVE A REPLY