Orile-ede Naijiria gbe abajade iwadii osuwon eto abere ajesara jade

Ronke Osundiya.

0
277
Eto abere ajesara

Orile-ede Naijiria ti gbe abajade iwadii osuwon eto abere ajesara fun ti odun 2016 si gbangba, fun awon omo orile-ede Naijiria.

Iwadii ohun fihan pe, eyokan ninu awon omo-wewe meta ni o gba abere ajesara naa pe.

Bakan-naa ni iwadii odun 2016 ohun ti fihan pe, iko ogooji ninu ida ogoorun awon omo-wewe ni ko tile lo sile-iwosan dipo, ti won yoo gba abere ajesara naa. Iwadii ohun ti fi kun pe, iko metalelogbon ninu ida ogoorun ni won gba ipele akoko abere ajesara naa, ti won ko si gba iyoku mo.

Nigba ti o n se agbekale esi-iwadii naa nibi ipade awon ti oro kan nilu Abuja, akowe agba ile-ise ti o ri si idagbasoke eto iwosan lorile-ede Naijiria, dokita Faisal Shuaib so pe, abajade iwadii yii yoo je ki ile-ise naa tunbo jara-mose ni abala abere ajesara naa.

Dokita Shuaib se lalaye pe, iwadii ohun yoo se atona siseto abere ajasara lojo-iwaju.

Nigba ti o n so erongba ipade naa, adele oga-agba eto ise-iwadii, dokita Abdullai Garba so pe, erongba ipade ohun ni lati wa ifowosowopo lori ona ati mu igberu ba ise-iwadii lorile-ede Naijiria

Dokita ohun fi kun oro re pe, erongba iwadii naa ni lati tun ran awon ti oro kan leti idi ti a gbodo fi mu igberu ba ipinnu isakoso ijoba lori abere ajesara lorile-ede yii.

O so fun awon ti oro kan pe:” Bi e se ni ile-itoju alaisan lowo, ti e n pese awon ohun elo itoju to peye, a nigbagbo pe, awon eniyan yii wa ni ikapa yin, fun idi eyi, eyin ni eni akoko ti o ye ko mo abajade iwadii abere ajesara ti odun 2016”.

Awon ti oro kan nibi ipade abajade iwadii abere ajesara ohun gborin fun akitiyan ile-ise naa fun ise takun-takun nipa gbegbe esi abajade iwadii ohun si gbangba fun awon omo-orile-ede Naijiria.

Asoju ile-ise eto-ilera lagbaye, abileko Rachel Seruyange so pe, orile-ede Naijiria ti n gbe igbese to nipon lati so aarun ropa-rose di afiseyin teegun n fiso lawujo.

Ninu iforo-wani-lenu wo pelu akoroyin ile akede Naijiria dokita Yusuf Yusufari ti ile-ise Bill and Mellinda so pe, bo ti le je pe, abajade esi iwadii ohun ko wu ni lori to, sibe a si le jara mose si lona ti yoo mori yiya wa.

Iwadii ohun fihan pe, awon ipinle kan gbe peeli ju awon miiran lo, ni eyi ti o so pe, ojuse ise ohun wa lowo awon ijoba ipinle.

 

Ronke Osundiya.

LEAVE A REPLY