Orile-ede Somalia se eto ibura f’awon omo ile igbimo asofin, lainaani bi opolopo se n fi edun okan han lori eto idibo naa

Abiodun Popoola, Abuja

0
46

Etalelogorin o lenigba awon omo ile igbimo asofin lorile-ede Somalia ni won bura fun lati soju awon eniyan won ninu ile igbimo asofin. Awon asofin mokanlelogun ti won dibo yan si ile igbimo asofin agba ati mejilelogoje ni ile igbimo aojusofin ni won kopa ninu ibura yii, to waye ni gbogan General Kahiye Police Academy, eyi ti agbenuso ile igbimo asofin to n kogba wole, Mohamed Sheikh Osman Jawari dari.
Ewee, eto idibo sile igbimo asofin mejeeji yoo si waye latari alekun ibujoko ni ile igbimo asofin agba ni ibamu pelu ofin oril-ede naa. Ajo isokan orile-ede Agbaye, Ajo isokan ile Afrika, Ajo isokan ile Europe ati awon alajosepo kaakiri gbogbo agbaye ni won fi edun okan won han lori alekun ijoko naa lori-ede Somalia
Won gba orile-ede naa ni imoran lapaapo ni ojo isegun Tuesday,
Alekun ijoko ile igbimo asofin yi ye ki o waye leyin eto idibo sipo Aare orile-ede naa pelu ibamu ofin orile-ede naa ni”
Awon ajo naa lagbaye gba orile-ede naa ni imoran wi pe, ki won bowo fun ofin
Eto idibo siipo Aare orile-ede naa to ye ko waye ni ojo kejidinlogun, osu kejila odun yii ni won ti sun siwaju, gege bii oro igbimo to n risi eto idibo lorile-ede Somalia,
Won ti dibo yan ijoko metalelaadorunlenigba ninu ile igbimo asofin orile-ede naa, awon ile igbimo asofin mejeeji ni yoo yan aare orile-ede naa.

Fi èsì sílẹ̀