Orile-ede Turkey fowo sinkun mu awon afurasi adunkokomoni mejilelogoji

Abiodun Popoola.

0
858
Turkey

Awon agbofinro lorile-ede Turkey ti fi awon eniyan ti won to mejilelogoji, eyi ti won fura si wipe won mo nipa awon adunkokomoni kakiri ekun lorile-ede naa sinu ihamo bi awon akoroyin naa seso.

Awon olopa fi awon afurasi ti won to mejilelogun, ti won je omo egbe alakatakiti elesin musulumi Islamic State ni apa ila oorun ilu Elazig miran sinu ihamo.

Yato si eyi,awon olopa ti fi awon eniyan ti won to ogun ni apa guusu ilu Adana,lori ibasepo pelu egbe oselu Kurdistan Workers Party (PKK), ti won ti fi ofin de sinu ihamo.

Bakan naa, awon alase orile-ede ohun si n wa awon afurasi mewa miran.

“Orile-ede Turkey ti fowo sinkun mu awon afurasi egberun lona maarun ti egbe alakatakiti elesin Islam ,ti won si ti da awon ara ile okeere ti won le ni egberun meta lati awon orile-ede marundinlogorun pada si awon orile-ede naa gege bi awon alase orile-ede Turkey se so.”

Bakan naa, won ti ko jale lati fun awon eniyan ti won le ni egberun lona mejidinlogoji ni anfaani lati wo orile-ede won.

Ni ojobo Thursday,awon alase lorile-ede Turkey fowo sinkun mu afurasi kan ti o je omo orile-ede Turkey leyin ti afurasi naa gbero lati lo ado oloro ja oko ofurufu orile-ede Amerika bo, ni papa awon ologun oju ofurufu ni ilu Incirlik.

Ijoba orile-ede naa lati mu igberu deba awon ilana lati gbogun ti egbe oselu PKK,ti o je ogbontarigi egbe adunkokomoni lorile-ede Turkey,ninu Ajo ile Europe ati orile-ede America lati igba ti won ti da ogun jija duro losu keje odun 2015.

Egbe oselu PKK se ifilole,iko adimora adunkokomoni tako orile-ede naa lodun 1984,ninu eyi ti awon eniyan ti won leni egberun lona ogoji ti so emi won nu.

 

 

Abiodun Popoola.

LEAVE A REPLY