Oshodi-Glover parowa fawon olopaa lati tubo sise sii

0
392

Igbakeji oga agba olopaa patapata loril-ede Naijiria to wa fun ekun iwo oorun guusu, Agboola Oshodi-Glover, ti parowa fawon olopaa lori ona iba-awon ara ilu soro bii omoluwabi ati ipa lati tubo gbiyanju sii lenu ise won. O ni eyi ni kokoro si aseyori fawon olopaa niran ti a wa yii.

Oshodi-Glover soro yii lasiko to n sabewo siko olopaa nipinle Osun ni kete ti komisona ipinle ohun, Fimihan Adeoye ti soro lori eto abo ipinle ohun tan. Adeoye ni ona isoro n gbesi to muwa omoluwabi dani nipinle naa n lo lati fi gbogunti isoro eto aabo nipa nini ajosepo to dan monran pelu awon olori eka kookan, awon lobaloba, awon olori elesin kookan. Komisona naa menuba awon aseyori olopaa nipinle naa ati awon ona ti won fi n fopin si iwa odaran.

Oshodi-Glover ninu oro ti re gbawon nimoran lati sora fun lilo ipa lori awon ara ilu. O ni ki won tele ilana omoluwabi lati ri ododo mu ki awon ara ilu le gbokan le won.  “O ye ki olopaa din lilo ipa ku ayafi to ba di dandan. Ki e bere si ni bowo fun eto ara ilu ki e si sise yin lai fi eto enikeni dun un”

Lasiko to n dahun awon ibeere lori ipese awon ohun amayerorun fawon olopaa lo ni ile ise ijoba to n risi oro awon olopaa lÁbuja n sa gbogbo ipa re lati mu nnkan rorun sii fawon agbofinro. O menuba apero lori eto aabo ti won se lAbuja laipe yii ni eyi tii won ti ko awon torokan lati sise bo ti ye ati sise ohun ti o to nigba gbogbo kaakiri orile-ede yii.

LEAVE A REPLY