Owo Diesel dinwo pelu ida mejilelogoji ninu ogorun

0
9513
Edinku de ba iye owo jala lita diesel

Owo epo diesel ti a tun mo si Automotive Gas Oil (AGO), ti fo kaakiri ipinle lorile-ede Naijria. Ogbeni Ndu Ughamadu, to je alakoso eka igbese to nii se pelu ara ilu fun ajo elepo robi NNPC ti kede edinku sowo epo diesel pe eyi waye lataari edinku to sele lati nnkan bii osu mefa seyin.

Ogbeni Ughamadu, ni lara awon igbëse naa ni sise atunse si pinpin epo naaa kiri sati ona pinipin epo naa.

O ni: Lati osu kin ni odun lati n sise takuntakun pelu awon toro kan lati pese epo kaakiri lasiko. Bakan naa ni ajo yii ti sise gidi lati tun awon opa epo se pelu awon ibudo fifo epo bii ti Atlas-Cove Mosimi, ti Port Harcourt ati Kaduna nibi ti a ti n fo epo robi gangan.

Gege bi o se so, igbese mii to tun bi eso rere fun edinwo yii ni ajosepo to ti n sanju ti tele lo to n sele laarin awon olokowo epo robi nlanla ninu egbe  MOMAN won ati NARTO to je tawon to ni oko ajagbe to n gbe epo ati awon PTD to n wa oko ajagbe to n pin epo robi kiri ati tawon osise aladani pelu epo robi ati oja tita inu re.

Atejade naa tun menuba igbese akoni to waye laarin banki Naijiria CBN ati ajo NNPC ti elepo robi ati afikun tijoba se lori riri owo dola ile okeere ta ati ra lasiko ni eyi to faaye gba epo diesel ati epo oko baalu ofurufu.

Ajo naa ti fi da gbogbo eniyan loju pe epo diesel atawon mii yoo wa ni arowoto koowa lasiko ki igbe aye awon  eniyan le tubo rorun sii.

Nibere odun yii ni won ta jala lita epo deisel kan ni oodunrun naira sugbon to dinku si naira marundinlogosan si igba naira losu karun un odun ni eyi to to odinwo mejilelogoji ninu ida ogorun, eyi ti awon ti depo naa ti dinwo si naira marundinlogoje si marundinlogojo fun jala lita kan

 

 

LEAVE A REPLY