Peter Edochie, Eekan ninu awon osere pe omo aadorin odun

0
38
Peter-Edochie pe aadorin odun

Okan gboogi lara awon osere ni Naijiria, Peter Edochie, pe omo aadorin odun lori oke eepe. Edochie ninu iforowanilenuwo pelu awon oniroyin Awka nipinle Anambra ni igbe aye alaafia ati jije ohun to ye lasiko se Pataki fun gbogbo eda.

O ni mimu ohun gbogbo lona to rorun ati fifi okan si nnkan ti eeyan ba n se je ki o ro oun lorun pupo ninu irin ajo aye oun. Edochie je okan lara awon gbajugbaja osere ile Adulawo to ti ko pa ninu opolopo fiimu agbelewo nile yii ati loke okun.

O bere ise pelu ile ise amohunmaworan ti Naijiria NTA ni ipinle Enugu ni guusu ila oorun Naijiria ki o to di agba oje  lodun 1980 nigba ti o kopa Pataki ninu iwe ti won so di ere “Things Fall Apart”.

O lo sile iwe alkobere St. Patrick ati St. James ni Zaria nipinle Kaduna. O kawe ni orile ede Naijiria ati loke okun bii Ile iwe ikoni nipa ise iroyin ati mohunmaworan nile Geesi. O gbe iyawo, o ni omo.

SHARE

Fi èsì sílẹ̀