SWAN da gbendeke fun iforukosile fodun 2017 gege bi omo egbe

0
21

Egbe awon onkoroyin nipa ere idaraya ti a mo si SWAN ti da gbandeke ogunjo osu keta fun iforukosile awon omo egbe tuntun fodun 2017. Akowe  agba egbe awon oniroyin ere idaraya naa, Olawale Alabi fi atejade sita nilu Abuja to fi gbendeke han fun awon omo egbe tuntun ati awon omo egbe to ye ko tun iforukosile se fodun yii..

O ni gbendeke yii yoo fun won ni anfaani lati sayewo to ye pelu awon oloye egbe nipinle kookan. Alabi ni won yoo se ayewo ki won to fun awon omo egbe naa ni kaadi idanimo to ye fun ojulowo omo egbe atawon mii. O ni eyi wa ni ibamu pelu ilana ti awon akoroyin lagbaye AIPS.

O ni o di dandan ki awon omo egbe to fe foruko sile lo se akosile to ye ni itakun agbaye ajo naa ki won le foruko sile bi o se ye.

SHARE

Fi èsì sílẹ̀