Won Ro Awon Adari Ile- Afirika Lati Se Amulo Awon Ohun Alumoni Won

Abiodun Popoola/Ademola Adepoju

0
436

Ipe ti lo sodo awon adari ile-Afirika lati se amulo awon ohun alumoni won fun idagbasoke eto oro-aje ni awon orile-ede ati ekun won.

Minista fun oro ile-okeere lorile-ede Naijiria, ogbeni Goeffrey Onyeama ni o pe ipe yii, lasiko ti o n gba asoju orile-ede Mali si orile-ede Naijiria ogbeni Muhamane Amadu Maiga lalejo nilu Abuja.

Minisita ohun fi edun okan re han, bi eto oro-aje se n se sege-sege laarin awon orile-ede ile-Afirika ati awon orile-ede miiran lagbaye.

O salaye pe, bi o tile je pe, ile- Afirika n pese awon ohun alumoni pupo, sibe, ida mewaa ninu ida ogoorun ni ile Afirika lo n janfaani re, nigba ti ida aadorun ninu ida ogorun n lo si awon orile-ede miiran lagbaye

O so pe: Ile Afirika n pese lopo-lopo amo, ibi tutu lo mo, a ko mu anfaani ati aleku baa won ohun ti a n pese, bakan naa ni a ko kara maisiki ati se aseyori ninu re, fun apere: a n pese koko, amo awon ti ko loko koko ni won jowo re, sugbon awon ti won n fi koko se awon ohun mimu bi sokoleeti, ni won je anfaani egbelemukun billionu owo dolla, awon orile-ede ti won je owo lori ohun mimu tii {tea} won ki I pese re,  Ile-Geesi ki I pese amo ti won je egbelemuku owo lori tea ju awon orile-ede ti won n pese tea julo.

Minisita ohun wa  ro awon odo ile Africa lati yera gigun le irin-ajo to lewu-ninu lo si ile-Europe ati awon orile-ede miiran lagbaye nipa wiwa awon ile olora.

Minisita ohun tenumo-on pe,”A nilati kuro ninu igbekun, bi a ba fe dekun  awon  omo wa lati gunle irinajo to lewu nipa igbiyanju atigba asale koja lo si ile Europe.o se ni laanu pe leyin igba odun ti a ti bo lowo oko eru, nigba ti awon kan  n wa si ile Afrika lati maa ko awon odo lo se ise fun won ni eyi to lodi si ife inu won , nibayii, awon odo ni won funra won sora won di eru ni awon orile  ede ohun”

Ni abala tire, asoju orile-ede Mali si orile-ede Naijiria, ogbeni Muhamane Amadu Maiga pe   awon  adari ajo awon orile-ede alajo sowopo ile Afirika {Economic Community of West Africa} (ECOWAS). Lati se amulo ipinnu ti won fenu-ko le lori lasiko ipade ijiroro ti won se lati se adinku isoro gbigbe awon eru jake-jado awon ekun orile-ede ti won je omo-egbe naa fun idagbasoke eto oro-aje ile-Africa.

Asoju ohun so pe: lasiko ipade ajo awon orile-ede alajo sowo-po apa iwo oorun Afirika, a ni ipele meta fun irin-ajo awon eniyan ati oja, ati paapaa awon osise eleto-abo. Mo lero pe, ko si isoro latigba ti a ti n se amulo ifenu-ko yi, ni eyi ti a nilo lati mu igberu ba ifenu-ko naa, awon agbofinro  ko gbodo je idiwo fun eto idokowo laarin awon orile-ede meji ati awon orile-ede yoku ni ile Afrika.

 

Abiodun Popoola/Ademola Adepoju

LEAVE A REPLY