Yemen kede ilu ko-fararo lori arun onigbameji to be sile

0
414

Orile-ede Yemen ti kede ilu ko fararo lataari arun onigbameji to be sile ni Sanaa to je olu ilu Yemen ni eyi ti o ti seku pa opolopo awon eniyan. Awon ile iwosan ti Awon omo ogun olote Houthi n samojuto re ti kun fun awon alaisan ti kolera n yo lenu.
Ajo Red Cross ni o ti le ni egberun mejo abo awon eniyan ti o ti yo lenu laarin ose kan. Ebi ati ogun abele lo tun je ki aisan naa tubo tan kale. Ida meji ninu meta awon eniyan naa ko ni anfaani si omi mimu to mo gaara.
Dominik Stillhart, to je oludari igbimo ajo agbaye fun Red Cross so fawon oniroyin ni Sanaa lana ojo Aiku pe eniyan marundinlogofa lo ti jalaisi lataari arun onigba meji naa lati ojo ketadinlogbon osu kerin si ojo ketala osu karun.
Ajo eleto ilera agbaye, WHO ni ekun Amanat al-Semah ni Sanaa ni arun naa ti n ba won finra julo bayii. Arun onigbameji je eyi ti omi ati ounje ti ko mo n fa ti eniyan yoo maa sunu ti yoo si maa bi.
O di igba keji ti arun kolera yoo be sile ni Yemen Lodun kan. Ajo WHO ni ida marundinlaadota ninu ida ogorun un awon ile iwosan lo n sise ni Yemen.
O to ile iwosan oodunrun ti won ti baje ninu ija laarin awon to n se tijoba Abdrabbuh Mansour Hadi ti awon eekan nile Saudi n satileyin fun ati awon omo ogun olote Houthi. O le ni Egberun aadota eniyan to ti farapa ninu ija naa lati osu keta odun 2015. Ti o le ni egberun mejo awon eniyan si ti gbemi mi. O le ni milionu mejidinlogun awon eniyan to nilo iranlowo bayii.

LEAVE A REPLY